Ìfihàn 17:8-14 BM

8 Ẹranko tí o rí yìí ti wà láàyè nígbà kan rí, ṣugbọn kò sí láàyè mọ́ nisinsinyii. Ṣugbọn ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò, tí yóo gòkè wá láti inú ọ̀gbun jíjìn, tí yóo wá lọ sí ibi ègbé. Nígbà tí wọ́n bá rí ẹranko náà ẹnu yóo ya àwọn tí ó ń gbé orí ilẹ̀ ayé, tí a kò kọ orúkọ wọn sinu ìwé ìyè láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wá, nítorí ó ti wà láàyè, ṣugbọn kò sí láàyè nisinsinyii, ṣugbọn yóo tún pada yè.

9 “Ọ̀rọ̀ yìí gba ọgbọ́n. Orí meje tí ẹranko náà ní jẹ́ òkè meje tí obinrin náà jókòó lé lórí. Wọ́n tún jẹ́ ọba meje.

10 Marun-un ninu wọn ti kú. Ọ̀kan wà lórí oyè nisinsinyii. Ọ̀kan yòókù kò ì tíì jẹ. Nígbà tí ó bá jọba, àkókò díẹ̀ ni yóo ṣe lórí oyè.

11 Ẹranko tí ó ti wà láàyè rí, tí kò sí mọ́, ni ẹkẹjọ, ṣugbọn ó wà ninu àwọn meje tí ń lọ sinu ègbé.

12 “Àwọn ìwo mẹ́wàá tí o rí jẹ́ ọba mẹ́wàá. Ṣugbọn wọn kò ì tíì joyè. Wọn óo gba àṣẹ fún wakati kan, àwọn ati ẹranko náà ni yóo jọ lo àṣẹ náà.

13 Ète kanṣoṣo ni wọ́n ní. Wọn yóo fi agbára wọn ati àṣẹ wọn fún ẹranko náà.

14 Wọn yóo bá Ọ̀dọ́ Aguntan náà jagun, ṣugbọn Ọ̀dọ́ Aguntan náà yóo ṣẹgun wọn nítorí pé òun ni Oluwa àwọn oluwa ati Ọba àwọn ọba. Àwọn tí wọ́n wà pẹlu Ọ̀dọ́ Aguntan náà ninu ìjà ati ìṣẹ́gun náà ni àwọn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́, tí a pè, tí a sì yàn.”