5 Ẹni tí ó bá ṣẹgun ni a óo wọ̀ ní aṣọ funfun bẹ́ẹ̀. N kò ní pa orúkọ rẹ̀ rẹ́ kúrò ninu ìwé ìyè. N óo jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀ níwájú Baba mi ati níwájú àwọn angẹli rẹ̀.
6 “Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.
7 “Kọ ìwé yìí sí angẹli ìjọ Filadẹfia pé:“Ẹni mímọ́ ati olóòótọ́ nì, ẹni tí kọ́kọ́rọ́ Dafidi ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀, tíí ṣí ìlẹ̀kùn tí ẹnikẹ́ni kò lè tì í, tíí sìí tìlẹ̀kùn tí ẹnikẹ́ni kò lè ṣí i, ó ní:
8 Mo mọ iṣẹ́ rẹ. Wò ó! Mo fi ìlẹ̀kùn kan tí ó ṣí sílẹ̀ siwaju rẹ, tí ẹnikẹ́ni kò lè tì. Mo mọ̀ pé agbára rẹ kéré, sibẹ o ti pa ọ̀rọ̀ mi mọ́. O kò sẹ́ orúkọ mi.
9 N óo fi àwọn kan láti inú ilé ìpàdé Satani lé ọ lọ́wọ́, àwọn òpùrọ́ tí wọn ń pe ara wọn ní Juu, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kì í ṣe Juu. N óo ṣe é tí wọn yóo fi wá sọ́dọ̀ rẹ, wọn yóo foríbalẹ̀ fún ọ, wọn yóo sì mọ̀ pé mo fẹ́ràn rẹ.
10 Nítorí o ti fi ìfaradà pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, Èmi náà yóo pa ọ́ mọ́ ní àkókò ìdánwò tí ń bọ̀ wá bá ayé, nígbà tí a óo dán gbogbo àwọn tí ó ń gbé inú ayé wò.
11 Mò ń bọ̀ kíákíá. Di ohun tí ń bẹ lọ́wọ́ rẹ mú ṣinṣin, kí ẹnikẹ́ni má baà gba adé rẹ.