10 Bí ẹ bá dáríjì ẹnikẹ́ni, èmi náà dáríjì í. Nítorí tí mo bá ti dáríjì eniyan, (bí nǹkankan bá fi ìgbà kan wà tí mo fi níláti dáríjì ẹnikẹ́ni), mo ṣe é nítorí tiyín níwájú Kristi.
11 Nítorí a kò gbọdọ̀ gba Èṣù láyè láti lò wá, nítorí a kò ṣàì mọ ète rẹ̀.
12 Nígbà tí mo dé Tiroasi láti waasu ìyìn rere Kristi, Oluwa ṣínà fún mi láti ṣiṣẹ́.
13 Ṣugbọn ọkàn mi kò balẹ̀ nígbà tí n kò rí Titu arakunrin mi níbẹ̀. Mo bá dágbére fún àwọn eniyan níbẹ̀, mo lọ sí Masedonia.
14 Ṣugbọn ọpẹ́ ni fún Ọlọrun tí ó jẹ́ kí á lè wà ninu àjọyọ̀ ìṣẹ́gun tí Kristi ṣẹgun, nígbà gbogbo. Ọlọrun náà ni ó tún ń mú kí ìmọ̀ rẹ̀ tí ń jáde láti ara wa máa gba gbogbo ilẹ̀ káàkiri bí òórùn dídùn níbi gbogbo.
15 Nítorí àwa ni òórùn dídùn tí Kristi fi rúbọ sí Ọlọrun lọ́dọ̀ àwọn tí à ń gbàlà ati àwọn tí ń ṣègbé.
16 Fún àwọn tí wọn ń ṣègbé, a dàbí òórùn tí n pani, ṣugbọn fún àwọn tí à ń gbàlà, a dàbí òórùn dídùn tí ó ń fún wọn ní ìyè. Ta ló tó ṣe irú iṣẹ́ yìí?