8 Mo bẹ̀ yín pé kí ẹ jẹ́ kí ó mọ̀ pé ẹ fẹ́ràn òun.
9 Ìdí tí mo fi kọ ìwé sí yín ni láti fi dán yín wò, kí n lè mọ̀ bí ẹ bá ń gbọ́ràn sí mi lẹ́nu ninu ohun gbogbo.
10 Bí ẹ bá dáríjì ẹnikẹ́ni, èmi náà dáríjì í. Nítorí tí mo bá ti dáríjì eniyan, (bí nǹkankan bá fi ìgbà kan wà tí mo fi níláti dáríjì ẹnikẹ́ni), mo ṣe é nítorí tiyín níwájú Kristi.
11 Nítorí a kò gbọdọ̀ gba Èṣù láyè láti lò wá, nítorí a kò ṣàì mọ ète rẹ̀.
12 Nígbà tí mo dé Tiroasi láti waasu ìyìn rere Kristi, Oluwa ṣínà fún mi láti ṣiṣẹ́.
13 Ṣugbọn ọkàn mi kò balẹ̀ nígbà tí n kò rí Titu arakunrin mi níbẹ̀. Mo bá dágbére fún àwọn eniyan níbẹ̀, mo lọ sí Masedonia.
14 Ṣugbọn ọpẹ́ ni fún Ọlọrun tí ó jẹ́ kí á lè wà ninu àjọyọ̀ ìṣẹ́gun tí Kristi ṣẹgun, nígbà gbogbo. Ọlọrun náà ni ó tún ń mú kí ìmọ̀ rẹ̀ tí ń jáde láti ara wa máa gba gbogbo ilẹ̀ káàkiri bí òórùn dídùn níbi gbogbo.