6 Ẹ ranti pé ẹni tí ó bá fúnrúgbìn díẹ̀, díẹ̀ ni yóo kórè. Ẹni tí ó bá fúnrúgbìn pupọ, pupọ ni yóo kórè.
7 Kí olukuluku ṣe bí ó bá ti pinnu ninu ọkàn rẹ̀, kì í ṣe pẹlu ìkanra, tabi àfipáṣe, nítorí onínúdídùn ọlọ́rẹ ni Ọlọrun fẹ́.
8 Ọlọrun lè fun yín ní oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn, tí ẹ óo fi ní ànító ninu ohun gbogbo nígbà gbogbo. Ẹ óo sì tún ní tí yóo ṣẹ́kù fún ohun rere gbogbo.
9 Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ẹnìkan lawọ́, ó ń ta àwọn talaka lọ́rẹ, iṣẹ́ àánú rẹ̀ wà títí.”
10 Ṣugbọn ẹni tí ó ń pèsè irúgbìn fún afunrugbin, tí ó tún ń pèsè oúnjẹ fún jíjẹ, yóo pèsè èso lọpọlọpọ fun yín, yóo sì mú kí àwọn èso iṣẹ́ àánú yín pọ̀ sí i.
11 Ẹ óo jẹ́ ọlọ́rọ̀ ní gbogbo ọ̀nà tí ẹ óo fi lè máa lawọ́ nígbà gbogbo. Ọpọlọpọ eniyan yóo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nígbà tí a bá fún wọn ní ẹ̀bùn tí ẹ gbé kalẹ̀ nítorí ìlawọ́ yín.
12 Nítorí kì í ṣe àìní àwọn onigbagbọ nìkan ni iṣẹ́ ìsìn yìí yóo pèsè fún, ṣugbọn yóo mú kí ọpọlọpọ eniyan máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun.