1 Ní àkókò náà Jesu ń la oko ọkà kan kọjá ní Ọjọ́ Ìsinmi àwọn Juu. Ebi ń pa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí já ọkà, wọ́n ń jẹ ẹ́.
2 Nígbà tí àwọn Farisi rí i, wọ́n wí fún un pé, “Wò ó! Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ ń ṣe ohun tí kò tọ́ láti ṣe ní Ọjọ́ Ìsinmi.”
3 Ṣugbọn Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ kò kà nípa ohun tí Dafidi ṣe nígbà tí ebi ń pa òun ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀?
4 Bí wọ́n ti wọ inú ilé Ọlọrun lọ, tí wọ́n sì jẹ burẹdi tí ó wà lórí tabili níwájú Oluwa, èyí tí ó lòdì sí òfin fún òun ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ láti jẹ bíkòṣe fún àwọn alufaa nìkan?