11 Wọ́n gbé orí rẹ̀ wá ninu àwo pẹrẹsẹ, wọ́n gbé e fún ọdọmọbinrin náà. Ó bá lọ gbé e fún ìyá rẹ̀.
12 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu bá wá, wọ́n gbé òkú rẹ̀ lọ, wọ́n sin ín; wọ́n sì lọ ròyìn fún Jesu.
13 Nígbà tí Jesu gbọ́, ó wọ ọkọ̀ ojú omi kúrò níbẹ̀ lọ sí ibìkan tí eniyan kò sí, kí ó lè dá wà. Nígbà tí àwọn eniyan gbọ́, wọ́n gba ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀ láti ìlú wọn, wọ́n tẹ̀lé e.
14 Bí ó ti ń gúnlẹ̀, ó rí ọ̀pọ̀ eniyan. Àánú wọn ṣe é, ó bá wo àwọn tí wọ́n ṣàìsàn ninu wọn sàn.
15 Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n ní, “Aṣálẹ̀ ni ibí yìí, ọjọ́ sì ti lọ. Fi àwọn eniyan wọnyi sílẹ̀ kí wọ́n lè lọ ra oúnjẹ fún ara wọn ninu àwọn ìletò.”
16 Ṣugbọn Jesu sọ fún wọn pé, “Kò yẹ kí wọ́n lọ; ẹ fún wọn ní oúnjẹ jẹ.”
17 Wọ́n dá a lóhùn pé, “Kò sí oúnjẹ níhìn-ín, àfi burẹdi marun-un ati ẹja meji.”