7 Lẹ́yìn tí wọ́n ti forí-korí, wọ́n fi owó náà ra ilẹ̀ amọ̀kòkò fún ìsìnkú àwọn àlejò.
8 Ìdí nìyí ti a fi ń pe ilẹ̀ náà ní, “Ilẹ̀ ẹ̀jẹ̀” títí di òní olónìí.
9 Báyìí ni ohun tí wolii Jeremaya, wí ṣẹ, nígbà tí ó sọ pé, “Wọ́n mú ọgbọ̀n owó fadaka náà, iye tí a dá lé orí ẹ̀mí náà, nítorí iye tí àwọn ọmọ Israẹli ń dá lé eniyan lórí nìyí,
10 wọ́n lo owó náà fún ilẹ̀ amọ̀kòkò, gẹ́gẹ́ bí Oluwa ti pàṣẹ fún mi.”
11 Jesu bá dúró siwaju gomina. Gomina bi í pé, “Ìwọ ni ọba àwọn Juu bí?”Jesu ní, “O ti fi ẹnu ara rẹ sọ ọ́.”
12 Ṣugbọn bí àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà ti ń fi ẹ̀sùn kàn án tó, kò fèsì rárá.
13 Nígbà náà ni Pilatu sọ fún un pé, “O kò gbọ́ irú ẹ̀sùn tí wọn ń fi kàn ọ́ ni?”