16 Ṣugbọn kì í ṣe gbogbo wọn ni ó gba ìyìn rere yìí gbọ́. Aisaya ṣá sọ ọ́ pé, “Oluwa, ta ni ó gba ohun tí a sọ gbọ́?”
17 Ṣebí ohun tí a bá gbọ́ ni à ń gbàgbọ́, ohun tí a sì gbọ́ yìí ni ọ̀rọ̀ Kristi?
18 Mo wá ń bèèrè, “Ṣé wọn kò ì tíì gbọ́ ni?” Wọ́n kúkú ti gbọ́, nítorí a rí i kà ninu Ìwé Mímọ́ pé,“Ìró wọn ti dé gbogbo orílẹ̀-èdè,àní, ọ̀rọ̀ wọn ti dé òpin ayé.”
19 Mo tún bèèrè: Àbí Israẹli kò mọ̀ ni? Ẹ jẹ́ kí á gbọ́ ohun tí Mose kọ́kọ́ sọ; ó ní,“N óo jẹ́ kí àwọn tí kì í ṣe orílẹ̀-èdè mu yín jowú,N óo sì jẹ́ kí orílẹ̀-èdè tí kò lóye mú kí ara ta yín.”
20 Aisaya pàápàá kò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ kọ́ òun lẹ́nu, ó ní,“Àwọn tí kò wá mi ni wọ́n rí mi,àwọn tí kò bèèrè mi ni mo fi ara hàn fún.”
21 Ṣugbọn ohun tí ó ní Ọlọrun wí fún Israẹli ni pé, “Láti òwúrọ̀ títí di alẹ́ ni mo na ọwọ́ mi sí àwọn aláìgbọràn ati alágídí eniyan.”