2 Awọn ọlọ̀tẹ si jinlẹ ni pipanirun, emi o jẹ olùbawi gbogbo wọn.
3 Emi mọ̀ Efraimu, Israeli kò si pamọ́ fun mi: nitori nisisiyi, Efraimu, iwọ ṣe agbère, Israeli si dibajẹ.
4 Iṣe wọn kì o jọ̀wọ wọn lati yipadà si Ọlọrun wọn: nitori ẹmi agbère wà lãrin wọn, nwọn kò si mọ̀ Oluwa.
5 A si rẹ̀ ogo Israeli silẹ loju ara rẹ̀; nitorina ni Israeli ati Efraimu yio ṣubu ninu aiṣedẽde wọn, Juda yio si ṣubu pẹlu wọn.
6 Nwọn o lọ ti awọn ti agbo-ẹran wọn ati ọ̀wọ ẹran wọn lati wá Oluwa: ṣugbọn nwọn kì o ri i, on ti fà ara rẹ̀ sẹhìn kuro lọdọ wọn.
7 Nwọn ti hùwa arekerekè si Oluwa: nitori nwọn ti bi ajèji ọmọ: nisisiyi li oṣù titun yio jẹ wọn run, pẹlu ipin wọn.
8 Ẹ fun korneti ni Gibea, ati ipè ni Rama; kigbe kikan ni Bet-afeni, lẹhìn rẹ, iwọ Benjamini.