6 Nwọn o lọ ti awọn ti agbo-ẹran wọn ati ọ̀wọ ẹran wọn lati wá Oluwa: ṣugbọn nwọn kì o ri i, on ti fà ara rẹ̀ sẹhìn kuro lọdọ wọn.
7 Nwọn ti hùwa arekerekè si Oluwa: nitori nwọn ti bi ajèji ọmọ: nisisiyi li oṣù titun yio jẹ wọn run, pẹlu ipin wọn.
8 Ẹ fun korneti ni Gibea, ati ipè ni Rama; kigbe kikan ni Bet-afeni, lẹhìn rẹ, iwọ Benjamini.
9 Efraimu yio di ahoro li ọjọ ibawi: ninu awọn ẹyà Israeli li emi ti fi ohun ti o wà nitõtọ hàn.
10 Awọn olori Juda dàbi awọn ti o yẹ̀ oju àla: lara wọn li emi o tú ibinu mi si bi omi.
11 A tẹ̀ ori Efraimu ba, a si ṣẹgun rẹ̀ ninu idajọ, nitoriti on mọ̃mọ̀ tẹ̀le ofin na.
12 Nitorina ni emi o ṣe dabi kòkoro aṣọ si Efraimu, ati si ile Juda bi idin.