1 AHABU si ni ãdọrin ọmọ ọkunrin ni Samaria. Jehu si kọwe, o si ranṣẹ si Samaria si awọn olori Jesreeli, si awọn àgbagba, ati si awọn ti ntọ́ awọn ọmọ Ahabu, wipe,
2 Njẹ nisisiyi nigbati iwe yi ba ti de ọdọ nyin, bi o ti jẹpe, awọn ọmọ oluwa nyin mbẹ lọdọ nyin, ati kẹkẹ́ ati ẹṣin mbẹ lọdọ nyin, ilu olodi pẹlu ati ihamọra.
3 Ki ẹ wò ẹniti o sàn jùlọ ati ti o si yẹ jùlọ ninu awọn ọmọ oluwa nyin, ki ẹ gbé e ka ori-itẹ́ baba rẹ̀, ki ẹ si jà fun ile oluwa nyin.
4 Ṣugbọn ẹ̀ru bà wọn gidigidi, nwọn si wipe, Kiyesi i, ọba meji kò duro niwaju rẹ̀: awa o ha ti ṣe le duro?