2. A. Ọba 10:19-25 YCE

19 Njẹ nitorina, ẹ pè gbogbo awọn woli Baali fun mi, gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀, ati gbogbo awọn alufa rẹ̀; máṣe jẹ ki ọkan ki o kù; nitoriti mo ni ẹbọ nla iṣe si Baali: ẹnikẹni ti o ba kù, kì yio yè. Ṣugbọn Jehu fi ẹ̀tan ṣe e, nitori ki o le pa awọn olùsin Baali run.

20 Jehu si wipe, Ẹ yà apejọ si mimọ́ fun Baali; nwọn si kede rẹ̀.

21 Jehu si ranṣẹ si gbogbo Israeli; gbogbo awọn olùsin Baali si wá tobẹ̃ ti kò si kù ọkunrin kan ti kò wá. Nwọn si wá sinu ile Baali; ile Baali si kún lati ikangun ekini titi de ekeji.

22 On si wi fun ẹniti o wà lori yará babaloriṣa pe, Kó aṣọ wá fun gbogbo awọn olùsin Baali. On si kó aṣọ jade fun wọn wá.

23 Jehu si lọ, ati Jehonadabu ọmọ Rekabu sinu ile Baali, o si wi fun awọn olùsin Baali pe, Ẹ wá kiri, ki ẹ si wò ki ẹnikan ninu awọn iranṣẹ Oluwa ki o má si pẹlu nyin nihin, bikòṣe kìki awọn olùsin Baali.

24 Nigbati nwọn si wọle lati ru ẹbọ ati ọrẹ-sisun, Jehu yàn ọgọrin ọkunrin si ode, o si wipe, Bi ẹnikan ninu awọn ọkunrin ti mo mu wá fi le nyin lọwọ ba lọ, ẹniti o ba jẹ ki o lọ, ẹmi rẹ̀ yio lọ fun ẹmi tirẹ̀.

25 O si ṣe, bi a si ti pari ati ru ẹbọ sisun, ni Jehu wi fun awọn olùṣọ ati awọn olori-ogun pe, Wọle, ki ẹ si pa wọn; ẹ máṣe jẹ ki ẹnikan ki o jade. Nwọn si fi oju idà pa wọn; awọn olùṣọ ati awọn olori-ogun si gbé wọn sọ si ode, nwọn si wọ̀ inu odi ile Baali.