2. A. Ọba 10:5-11 YCE

5 Ati ẹniti iṣe olori ile, ati ẹniti iṣe olori ilu, awọn àgbagba pẹlu, ati awọn olutọ́ awọn ọmọ, ranṣẹ si Jehu wipe, Iranṣẹ rẹ li awa, a o si ṣe gbogbo ohun ti o ba pa li aṣẹ fun wa; awa kì yio jẹ ọba: iwọ ṣe eyi ti o dara li oju rẹ.

6 Nigbana ni o kọ iwe lẹrinkeji si wọn wipe, Bi ẹnyin ba ṣe ti emi, bi ẹnyin o si fi eti si ohùn mi, ẹ mu ori awọn ọkunrin na, awọn ọmọ oluwa nyin, ki ẹ si tọ̀ mi wá ni Jesreeli ni iwòyi ọla. Njẹ awọn ọmọ ọba, ãdọrin ọkunrin, mbẹ pẹlu awọn enia nla ilu na ti ntọ́ wọn.

7 O si ṣe, nigbati iwe na de ọdọ wọn, ni nwọn mu awọn ọmọ ọba, nwọn si pa ãdọrin ọkunrin, nwọn si kó ori wọn sinu agbọ̀n, nwọn si fi wọn ranṣẹ si i ni Jesreeli.

8 Onṣẹ kan si de, o si sọ fun u, wipe, nwọn ti mu ori awọn ọmọ ọba wá. On si wipe, Ẹ tò wọn li okiti meji ni atiwọ̀ ẹnu bodè, titi di owurọ̀.

9 O si ṣe li owurọ̀, o si jade lọ, o si duro, o si wi fun gbogbo awọn enia pe, Olododo li ẹnyin: kiyesi i, emi ṣọ̀tẹ si oluwa mi, mo si pa a: ṣugbọn tani pa gbogbo awọn wọnyi?

10 Njẹ ẹ mọ̀ pe, kò si ohunkan ninu ọ̀rọ Oluwa, ti Oluwa sọ niti ile Ahabu ti yio bọ́ silẹ, nitori ti Oluwa ti ṣe eyi ti o ti sọ nipa ọwọ Elijah iranṣẹ rẹ̀.

11 Bẹ̃ni Jehu pa gbogbo awọn ti o kù ni ile Ahabu ni Jesreeli ati gbogbo awọn enia nla rẹ̀, ati awọn ibatan rẹ̀, ati awọn alufa rẹ̀, titi on kò fi kù ọkan silẹ fun u.