2 Jehoaṣi si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa li ọjọ rẹ̀ gbogbo ninu eyiti Jehoiada alufa nkọ́ ọ.
3 Kiki ibi giga wọnni ni a kò mu kuro: awọn enia nrubọ, nwọn si nsun turari sibẹ ni ibi giga wọnni.
4 Jehoaṣi si wi fun awọn alufa pe, Gbogbo owo ti a yà si mimọ́ ti a si mu wá sinu ile Oluwa, ani olukuluku owo ti o kọja, ati owo idiyele olukuluku, ati gbogbo owo ti o ti inu ọkàn olukuluku wá lati mu wá sinu ile Oluwa.
5 Ẹ jẹ ki awọn alufa ki o mu u tọ̀ ara wọn, olukuluku lati ọwọ ojulùmọ rẹ̀: ẹ si jẹ ki nwọn ki o tun ẹya ile na ṣe, nibikibi ti a ba ri ẹya.
6 O si ṣe, li ọdun kẹtalelogun Jehoaṣi ọba, awọn alufa kò iti tun ẹya ile na ṣe.
7 Nigbana ni Jehoaṣi ọba pè Jehoiada alufa, ati awọn alufa miràn, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin kò tun ẹya ile na ṣe? njẹ nisisiyi ẹ máṣe gbà owo mọ lọwọ awọn ojulùmọ nyin, bikòṣepe ki ẹ fi i lelẹ fun ẹya ile na.
8 Awọn alufa si ṣe ilerí lati má gbà owo lọwọ awọn enia mọ, tabi lati má tun ẹya ile na ṣe.