2. A. Ọba 17:13-19 YCE

13 Sibẹ Oluwa jẹri si Israeli, ati si Juda, nipa ọwọ gbogbo awọn woli, ati gbogbo awọn ariran, wipe, Ẹ yipada kuro ninu ọ̀na buburu nyin, ki ẹ si pa ofin mi ati ilana mi mọ́, gẹgẹ bi gbogbo ofin ti mo pa li aṣẹ fun awọn baba nyin, ti mo rán si nyin nipa ọwọ awọn woli iranṣẹ mi.

14 Sibẹ nwọn kò fẹ igbọ́, ṣugbọn nwọn mu ọrùn wọn le, gẹgẹ bi ọrùn awọn baba wọn, ti kò gbà Oluwa Ọlọrun wọn gbọ́.

15 Nwọn si kọ̀ ilana rẹ̀, ati majẹmu rẹ̀ silẹ, ti o ba awọn baba wọn dá, ati ẹri rẹ̀ ti o jẹ si wọn: nwọn si ntọ̀ ohun asan lẹhin, nwọn si huwa asan, nwọn si ntọ̀ awọn keferi lẹhin ti o yi wọn ka, niti ẹniti Oluwa ti kilọ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe ṣe bi awọn.

16 Nwọn si kọ̀ gbogbo ofin Oluwa Ọlọrun wọn silẹ, nwọn si ṣe ere didà fun ara wọn, ani, ẹgbọ̀rọ malu meji, nwọn si ṣe ere oriṣa, nwọn si mbọ gbogbo ogun ọrun, nwọn si sìn Baali.

17 Nwọn si mu ki awọn ọmọkunrin wọn ati ọmọbinrin wọn ki o kọja lãrin iná, nwọn si nfọ̀ afọ̀ṣẹ, nwọn si nṣe alupayida, nwọn si tà ara wọn lati ṣe ibi niwaju Oluwa, lati mu u binu.

18 Nitorina ni Oluwa ṣe binu si Israeli gidigidi, o si mu wọn kuro niwaju rẹ̀: ọkan kò kù bikòṣe ẹ̀ya Juda nikanṣoṣo.

19 Juda pẹlu kò pa aṣẹ Oluwa Ọlọrun wọn mọ́, ṣugbọn nwọn rìn ninu ilana Israeli ti nwọn ṣe.