36 Ṣugbọn Oluwa ti o mu nyin gòke ti ilẹ Egipti wá, pẹlu agbara nla ati ninà apá, on ni ki ẹ mã bẹ̀ru, on ni ki ẹ si mã tẹriba fun, on ni ki ẹ sì mã rubọ si.
37 Ati idasilẹ wọnni, ati ilàna wọnni, ati ofin ati aṣẹ ti o ti kọ fun nyin, li ẹnyin o mã kiyesi lati mã ṣe li ọjọ gbogbo; ẹnyin kò si gbọdọ bẹ̀ru awọn ọlọrun miràn.
38 Ati majẹmu ti mo ti ba nyin dá ni ẹnyin kò gbọdọ gbàgbe; bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ bẹ̀ru awọn ọlọrun miran.
39 Ṣugbọn Oluwa Ọlọrun nyin ni ẹnyin o mã bẹ̀ru; on ni yio si gbà nyin lọwọ awọn ọta nyin gbogbo.
40 Nwọn kò si gbọ́, ṣugbọn nwọn ṣe bi iṣe wọn atijọ.
41 Bẹ̃li awọn orilẹ-ède wọnyi bẹ̀ru Oluwa, ṣugbọn nwọn tun sin awọn ere fifin wọn pẹlu; awọn ọmọ wọn, ati awọn ọmọ-ọmọ wọn, bi awọn baba wọn ti ṣe, bẹ̃li awọn na nṣe titi fi di oni yi.