14 On si mu agbáda Elijah ti o bọ́ lọwọ rẹ̀, o si lù omi na, o si wipe, Nibo ni Oluwa Ọlọrun Elijah wà? Nigbati on pẹlu si lù omi na, nwọn si pinyà sihin ati sọhun: Eliṣa si rekọja.
15 Awọn ọmọ awọn woli ti o wà ni Jeriko nihà keji si ri i, nwọn si wipe, Ẹmi Elijah bà le Eliṣa. Nwọn si wá ipade rẹ̀; nwọn si tẹ̀ ara wọn ba silẹ niwaju rẹ̀.
16 Nwọn si wi fun u pe, Wò o na, ãdọta ọkunrin alagbara mbẹ pẹlu awọn iranṣẹ rẹ; awa bẹ̀ ọ, jẹ ki nwọn ki o lọ, ki nwọn ki o si wá oluwa rẹ lọ: bọya Ẹmi Oluwa ti gbé e sokè, o si ti sọ ọ sori ọkan ninu òke nla wọnni, tabi sinu afonifojì kan. On si wipe, Ẹ máṣe ranṣẹ.
17 Nigbati nwọn si rọ̀ ọ titi oju fi tì i, o wi fun wọn pe, Ranṣẹ. Nitorina nwọn rán ãdọta ọkunrin, nwọn si wá a ni ijọ mẹta, ṣugbọn nwọn kò ri i.
18 Nwọn si tun pada tọ̀ ọ wá, (nitori ni Jeriko li o joko,) o wi fun wọn pe, Emi kò ti wi fun nyin pe, Ẹ máṣe lọ?
19 Awọn ọkunrin ilu na si wi fun Eliṣa pe, Kiyesi i, itẹ̀do ilu yi dara, bi oluwa mi ti ri i: ṣugbọn omi buru, ilẹ si ṣá.
20 On si wipe, Mu àwokóto titun kan fun mi wá, si fi iyọ̀ sinu rẹ̀; nwọn si mu u tọ̀ ọ wá.