21 On si jade lọ si ibi orisun omi na, o si dà iyọ na sibẹ, o si wipe, Bayi li Oluwa wi, Emi ṣe àwotan omi wọnyi; lati ihin lọ, kì yio si ikú mọ, tabi aṣálẹ.
22 Bẹ̃ni a ṣe àwotan omi na titi di oni oloni, gẹgẹ bi ọ̀rọ Eliṣa ti o sọ.
23 O si gòke lati ibẹ lọ si Beteli: bi o si ti ngòke lọ li ọ̀na, awọn ọmọ kekeke jade lati ilu wá, nwọn si nfi ṣe ẹlẹyà, nwọn si wi fun u pe, Gòke lọ, apari! gòke lọ, apari!
24 O si yipada, o si wò wọn, o si fi wọn bú li orukọ Oluwa. Abo-beari meji si jade lati inu igbó wá, nwọn si fà mejilelogoji ya ninu wọn.
25 O si ti ibẹ lọ si òke Karmeli; ati lati ibẹ o pada si Samaria.