7 Isaiah si wipe, Mu odidi ọ̀pọtọ. Nwọn si mu u, nwọn si fi le õwo na, ara rẹ̀ si da.
8 Hesekiah si wi fun Isaiah pe, Kini yio ṣe àmi pe Oluwa yio wò mi sàn, ati pe emi o gòke lọ si ile Oluwa ni ijọ kẹta?
9 Isaiah si wipe, Àmi yi ni iwọ o ni lati ọdọ Oluwa wá, pe, Oluwa yio ṣe nkan yi ti on ti sọ: ki ojiji ki o lọ siwaju ni iṣisẹ̀ mẹwa ni, tabi ki o pada sẹhin ni iṣisẹ̀ mẹwa?
10 Hesekiah si dahùn wipe, Ohun ti o rọrùn ni fun ojiji ki o lọ siwaju ni iṣisẹ̀ mẹwa: bẹ̃kọ, ṣugbọn jẹ ki ojiji ki o pada sẹhin ni iṣisẹ̀ mẹwa.
11 Isaiah woli si kepè Oluwa; on si mu ojiji pada sẹhin ni iṣisẹ̀ mẹwa, nipa eyiti o ti sọ̀kalẹ ninu agogo-õrùn Ahasi.
12 Li akokò na ni Berodaki-Baladani, ọmọ Baladani, ọba Babeli, rán iwe ati ọrẹ si Hesekiah: nitoriti o ti gbọ́ pe Hesekiah ti ṣe aisàn.
13 Hesekiah si fi eti si ti wọn, o si fi gbogbo ile iṣura ohun iyebiye rẹ̀ hàn wọn, fadakà, ati wura, ati turari, ati ororo iyebiye, ati gbogbo ile ohun ihamọra rẹ̀, ati gbogbo eyiti a ri ninu iṣura rẹ̀: kò si nkan ni ile rẹ̀, tabi ni gbogbo ijọba rẹ̀, ti Hesekiah kò fi hàn wọn.