1 ẸNI ọdun mejila ni Manasse nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li ọdun marundilọgọta ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ ni Hefsiba.
2 O si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa, bi iṣe-irira ti awọn keferi, ti Oluwa tì jade niwaju awọn ọmọ Israeli.
3 Nitoriti o tun kọ́ ibi giga wọnni ti Hesekiah baba rẹ̀ ti parun; o si tẹ́ pẹpẹ fun Baali o si ṣe ere-oriṣa, bi Ahabu, ọba Israeli ti ṣe, o si mbọ gbogbo ogun ọrun, o si nsìn wọn.
4 O si tẹ́ pẹpẹ ni ile Oluwa, eyiti Oluwa ti sọ pe, Ni Jerusalemu li emi o fi orukọ mi si.
5 On si tẹ́ pẹpẹ fun gbogbo ogun ọrun li agbalá mejeji ile Oluwa.
6 On si mu ki ọmọ rẹ̀ ki o kọja lãrin iná, a si mã ṣe akiyesi afọṣẹ, a si mã ṣe alupàyida, a si mã bá awọn okú ati awọn oṣó lò: o hùwa buburu pupọ̀ li oju Oluwa lati mu u binu.
7 O si gbé ere oriṣa fifin kalẹ ti o ti ṣe ni ile na ti Oluwa sọ fun Dafidi ati Solomoni ọmọ rẹ̀ pe, Ni ile yi, ati ni Jerusalemu, ti mo ti yàn ninu gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli, li emi o fi orukọ mi si lailai: