12 Ọba si paṣẹ fun Hilkiah alufa, ati Ahikamu ọmọ Ṣafani, ati Akbori ọmọ Mikaiah, ati Ṣafani akọwe, ati Asahiah iranṣẹ ọba wipe,
13 Ẹ lọ, ẹ bère lọwọ Oluwa fun mi, ati fun awọn enia, ati fun gbogbo Juda, niti ọ̀rọ iwe yi ti a ri: nitori titobi ni ibinu Oluwa ti o rú si wa, nitori awọn baba wa kò fi eti si ọ̀rọ iwe yi, lati ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti a kọwe silẹ fun wa.
14 Bẹ̃ni Hilkiah alufa, ati Ahikamu, ati Akbori, ati Ṣafani, ati Asahiah tọ̀ Hulda woli obinrin lọ, aya Ṣallumu, ọmọ Tikfa, ọmọ Harhasi, alabojuto aṣọ (njẹ on ngbe Jerusalemu niha keji); nwọn si ba a sọ̀rọ.
15 On si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, Sọ fun ọkunrin ti o rán nyin si mi pe,
16 Bayi li Oluwa wi, Kiyesi i, emi o mu ibi bá ibiyi, ati bá awọn ara ilu na, ani gbogbo ọ̀rọ iwe na ti ọba Juda ti kà.
17 Nitoriti nwọn ti kọ̀ mi silẹ, nwọn si ti nsun turari fun awọn ọlọrun miran, ki nwọn ki o le fi gbogbo iṣẹ ọwọ wọn mu mi binu; nitorina ibinu mi yio rú si ibi yi, kì yio si rọlẹ.
18 Ṣugbọn fun ọba Juda ti o rán nyin wá ibère lọdọ Oluwa, bayi li ẹnyin o sọ fun u, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, niti ọ̀rọ wọnni ti iwọ ti gbọ́: