16 Bayi li Oluwa wi, Kiyesi i, emi o mu ibi bá ibiyi, ati bá awọn ara ilu na, ani gbogbo ọ̀rọ iwe na ti ọba Juda ti kà.
17 Nitoriti nwọn ti kọ̀ mi silẹ, nwọn si ti nsun turari fun awọn ọlọrun miran, ki nwọn ki o le fi gbogbo iṣẹ ọwọ wọn mu mi binu; nitorina ibinu mi yio rú si ibi yi, kì yio si rọlẹ.
18 Ṣugbọn fun ọba Juda ti o rán nyin wá ibère lọdọ Oluwa, bayi li ẹnyin o sọ fun u, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, niti ọ̀rọ wọnni ti iwọ ti gbọ́:
19 Nitoriti ọkàn rẹ rọ̀, ti iwọ si ti rẹ̀ ara rẹ silẹ niwaju Oluwa, nigbati iwọ gbọ́ eyiti mo sọ si ibi yi, ati si awọn ara ilu na pe, nwọn o di ahoro ati ẹni-ègun, ti iwọ si fà aṣọ rẹ ya, ti o si sọkun niwaju mi; emi pẹlu ti gbọ́ tirẹ, li Oluwa wi.
20 Nitorina kiyesi i, emi o kó ọ jọ sọdọ awọn baba rẹ, a o si kó ọ jọ sinu isà-okú rẹ li alafia; oju rẹ kì o si ri gbogbo ibi ti emi o mu wá bá ibi yi. Nwọn si tún mu èsi fun ọba wá.