7 Ṣugbọn a kò ba wọn ṣe iṣirò owo ti a fi le wọn lọwọ, nitoriti nwọn ṣe otitọ.
8 Hilkiah olori alufa si sọ fun Ṣafani akọwe pe, Emi ri iwe ofin ni ile Oluwa. Hilkiah si fi iwe na fun Ṣafani, on si kà a.
9 Ṣafani akọwe si wá sọdọ ọba, o si tún mu èsi pada fun ọba wá, o si wipe, Awọn iranṣẹ rẹ ti kó owo na jọ ti a ri ni ile na, nwọn si ti fi le ọwọ awọn ti o nṣiṣẹ na, ti nṣe alabojuto ile Oluwa.
10 Ṣafani akọwe si fi hàn ọba, pe, Hilkiah alufa fi iwe kan le mi lọwọ. Ṣafani si kà a niwaju ọba.
11 O si ṣe, nigbati ọba gbọ́ ọ̀rọ inu iwe ofin na, o si fà aṣọ rẹ̀ ya.
12 Ọba si paṣẹ fun Hilkiah alufa, ati Ahikamu ọmọ Ṣafani, ati Akbori ọmọ Mikaiah, ati Ṣafani akọwe, ati Asahiah iranṣẹ ọba wipe,
13 Ẹ lọ, ẹ bère lọwọ Oluwa fun mi, ati fun awọn enia, ati fun gbogbo Juda, niti ọ̀rọ iwe yi ti a ri: nitori titobi ni ibinu Oluwa ti o rú si wa, nitori awọn baba wa kò fi eti si ọ̀rọ iwe yi, lati ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti a kọwe silẹ fun wa.