2. A. Ọba 23:11-17 YCE

11 O si mu ẹṣin wọnni kuro ti awọn ọba Juda ti fi fun õrun, ni atiwọ̀ inu ile Oluwa lẹba iyẹ̀wu Natan-meleki iwẹ̀fa, ti o ti wà ni agbegbe tempili, o si fi iná sun kẹkẹ́ õrun wọnni.

12 Ati pẹpẹ wọnni ti mbẹ lori iyara òke Ahasi, ti awọn ọba Juda ti tẹ́, ati pẹpẹ wọnni ti Manasse ti tẹ́ li ãfin mejeji ile Oluwa ni ọba wó lulẹ, o si yara lati ibẹ, o si da ekuru wọn sinu odò Kidroni.

13 Ati ibi giga wọnni ti o wà niwaju Jerusalemu, ti o wà li ọwọ ọtún òke idibàjẹ, ti Solomoni ọba Israeli ti kọ́ fun Aṣtoreti ohun irira awọn ara Sidoni, ati fun Kemoṣi ohun irira awọn ara Moabu, ati fun Milkomu ohun-irira awọn ọmọ Ammoni li ọba sọ di ẽri.

14 O si fọ́ awọn ere na tũtu, o si wó awọn ere-oriṣa lulẹ, o si fi egungun enia kún ipò wọn.

15 Ati pẹlu, pẹpẹ ti o ti wà ni Beteli, ati ibi giga ti Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀, ti tẹ́, ati pẹpẹ na, ati ibi giga na ni o wó lulẹ, o si sun ibi giga na, o si lọ̀ ọ lũlu, o si sun ere-oriṣa na.

16 Bi Josiah si ti yira pada, o ri awọn isà-okú ti o wà lori òke, o si ranṣẹ, o si kó awọn egungun lati inu isà wọnni kuro, o si sun wọn lori pẹpẹ na, o si sọ ọ di ẽri, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti enia Ọlọrun nì ti kede, ẹniti o kede ọ̀ro wọnyi.

17 Nigbana li o wipe, Ọwọ̀n isa-okú wo li eyi ti mo ri nì? Awọn enia ilu na si sọ fun u pe, Isà-okú enia Ọlọrun nì ni, ti o ti Juda wá, ti o si kede nkan wọnyi ti iwọ ti ṣe si pẹpẹ Beteli.