23 Ṣugbọn li ọdun kejidilogun Josiah ọba, ni a pa irekọja yi mọ́ fun Oluwa ni Jerusalemu.
24 Ati pẹlu awọn ti mba awọn okú lò, ati awọn oṣo, ati awọn ere, ati awọn oriṣa, ati gbogbo irira ti a ri ni ilẹ Juda ati ni Jerusalemu ni Josiah kó kuro, ki o le mu ọ̀rọ ofin na ṣẹ ti a ti kọ sinu iwe ti Hilkiah alufa ri ni ile Oluwa.
25 Kò si si ọba kan ṣãju rẹ̀, ti o dabi rẹ̀, ti o yipada si Oluwa tinutinu ati tọkàntọkàn ati pẹlu gbogbo agbara rẹ̀, gẹgẹ bi gbogbo ofin Mose; bẹ̃ni lẹhin rẹ̀, kò si ẹnikan ti o dide ti o dàbi rẹ̀.
26 Ṣugbọn Oluwa kò yipada kuro ninu mimuná ibinu nla rẹ̀, eyiti ibinu rẹ̀ fi ràn si Juda, nitori gbogbo imunibinu ti Manasse ti fi mu u binu.
27 Oluwa si wipe, Emi o si mu Juda kuro loju mi pẹlu, bi mo ti mu Israeli kuro, emi o si ta ilu Jerusalemu yi nù, ti mo ti yàn, ati ile eyiti mo wipe, Orukọ mi yio wà nibẹ.
28 Ati iyokù iṣe Josiah ati gbogbo eyiti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda?
29 Li ọjọ rẹ̀ ni Farao-Neko ọba Egipti dide ogun si ọba Assiria li odò Euferate: Josiah ọba si dide si i; on si pa a ni Megiddo, nigbati o ri i.