31 Ẹni ọdun mẹtalelogun ni Jehoahasi nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba; o si jọba li oṣù mẹta ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ ni Hamutali, ọmọbinrin Jeremiah ti Libna,
32 On si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti awọn baba rẹ̀ ti ṣe.
33 Farao-Neko si fi i sinu idè ni Ribla, ni ilẹ Hamati, ki o má ba jọba ni Jerusalemu; o si fi ilẹ na si abẹ isìn li ọgọrun talenti fadakà, ati talenti wura.
34 Farao-Neko si fi Eliakimu ọmọ Josiah jẹ ọba ni ipò Josiah baba rẹ̀, o si pa orukọ rẹ̀ dà si Jehoiakimu, o si mu Jehoahasi kuro; on si wá si Egipti, o si kú nibẹ.
35 Jehoiakimu si fi fadakà ati wura na fun Farao; ṣugbọn o bu owo-odè fun ilẹ na lati san owo na gẹgẹ bi ofin Farao: o fi agbara gbà fadakà ati wurà na lọwọ awọn enia ilẹ na, lọwọ olukuluku gẹgẹ bi owo ti a bù fun u, lati fi fun Farao-Neko.
36 Ẹni ọdun mẹ̃dọgbọ̀n ni Jehoiakimu nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba; o si jọba ọdun mọkanla ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ ni Sebuda, ọmọbinrin Bedaiah ti Ruma.
37 On si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti awọn baba rẹ̀ ti ṣe.