2. A. Ọba 23:5-11 YCE

5 O si dá awọn baba-loriṣa lẹkun, ti awọn ọba Juda ti yàn lati ma sun turari ni ibi giga ni ilu Juda wọnni, ati ni ibi ti o yi Jerusalemu ka; awọn pẹlu ti nsun turari fun Baali, fun õrùn, ati fun òṣupa, ati fun awọn àmi mejila ìrawọ, ati fun gbogbo ogun ọrun.

6 O si gbé ere-oriṣa jade kuro ni ile Oluwa, sẹhin ode Jerusalemu lọ si odò Kidroni, o si sun u nibi odò Kidroni, o si lọ̀ ọ lũlu, o si dà ẽrú rẹ̀ sori isà-okú awọn ọmọ enia na.

7 O si wó ile awọn ti nhù ìwa panṣaga, ti mbẹ leti ile Oluwa, nibiti awọn obinrin wun aṣọ-agọ fun ere-oriṣa.

8 O si kó gbogbo awọn alufa jade kuro ni ilu Juda wọnni, o si sọ ibi giga wọnni di ẽri nibiti awọn alufa ti sun turari, lati Geba titi de Beer-ṣeba, o si wó ibi giga ẹnu-ibodè wọnni ti mbẹ ni atiwọ̀ ẹnu-ibodè Joṣua bãlẹ ilu, ti mbẹ lapa osi ẹni, ni atiwọ̀ ẹnu-ibode ilu.

9 Ṣugbọn awọn alufa ibi giga wọnni kò gòke wá si ibi pẹpẹ Oluwa ni Jerusalemu, ṣugbọn nwọn jẹ ninu àkara alaiwu lãrin awọn arakunrin wọn.

10 On si sọ Tofeti di ẽri, ti mbẹ ni afonifojì awọn ọmọ Hinnomu, ki ẹnikan ki o máṣe mu ọmọ rẹ̀ ọkunrin, tabi ọmọ rẹ̀ obinrin là ãrin iná kọja fun Moleki.

11 O si mu ẹṣin wọnni kuro ti awọn ọba Juda ti fi fun õrun, ni atiwọ̀ inu ile Oluwa lẹba iyẹ̀wu Natan-meleki iwẹ̀fa, ti o ti wà ni agbegbe tempili, o si fi iná sun kẹkẹ́ õrun wọnni.