15 Ṣugbọn ẹ mu akọrin kan fun mi wá nisisiyi. O si ṣe, nigbati akọrin na nkọrin, ọwọ Oluwa si bà le e.
16 On si wipe, Bayi li Oluwa wi, Wà iho pupọ li afonifojì yi.
17 Nitori bayi li Oluwa wi, pe, Ẹnyin kì o ri afẹfẹ, bẹ̃ni ẹnyin kì o ri òjo; ṣugbọn afonifojì na yio kún fun omi, ki ẹnyin ki o le mu, ati ẹnyin, ati awọn ẹran-ọ̀sin nyin, ati ẹran nyin.
18 Ohun kikini si li eyi loju Oluwa: on o fi awọn ara Moabu le nyin lọwọ pẹlu.
19 Ẹnyin o si kọlù gbogbo ilu olodi, ati gbogbo ãyò ilu, ẹnyin o si ké gbogbo igi rere lulẹ, ẹnyin o si dí gbogbo kanga omi, ẹnyin o si fi okuta bà gbogbo oko rere jẹ.
20 O si ṣe li owurọ, bi a ti nta ọrẹ-ẹbọ onjẹ, si kiyesi i, omi ti ọ̀na Edomu wá, ilẹ na si kún fun omi.
21 Nigbati gbogbo ara Moabu gbọ́ pe, awọn ọba gòke wá lati ba wọn jà, nwọn kó gbogbo awọn ti o le hamọra ogun jọ, ati awọn ti o dagba jù wọn lọ, nwọn si duro li eti ilẹ wọn.