17 Nitori bayi li Oluwa wi, pe, Ẹnyin kì o ri afẹfẹ, bẹ̃ni ẹnyin kì o ri òjo; ṣugbọn afonifojì na yio kún fun omi, ki ẹnyin ki o le mu, ati ẹnyin, ati awọn ẹran-ọ̀sin nyin, ati ẹran nyin.
18 Ohun kikini si li eyi loju Oluwa: on o fi awọn ara Moabu le nyin lọwọ pẹlu.
19 Ẹnyin o si kọlù gbogbo ilu olodi, ati gbogbo ãyò ilu, ẹnyin o si ké gbogbo igi rere lulẹ, ẹnyin o si dí gbogbo kanga omi, ẹnyin o si fi okuta bà gbogbo oko rere jẹ.
20 O si ṣe li owurọ, bi a ti nta ọrẹ-ẹbọ onjẹ, si kiyesi i, omi ti ọ̀na Edomu wá, ilẹ na si kún fun omi.
21 Nigbati gbogbo ara Moabu gbọ́ pe, awọn ọba gòke wá lati ba wọn jà, nwọn kó gbogbo awọn ti o le hamọra ogun jọ, ati awọn ti o dagba jù wọn lọ, nwọn si duro li eti ilẹ wọn.
22 Nwọn si dide li owurọ̀, õrùn si ràn si oju omi na, awọn ara Moabu si ri omi na li apakeji, o pọn bi ẹ̀jẹ:
23 Nwọn si wipe, Ẹ̀jẹ li eyi: awọn ọba na run: nwọn si ti pa ara wọn; njẹ nisisiyi, Moabu, dide si ikogun.