2. A. Ọba 5:11-17 YCE

11 Ṣugbọn Naamani binu, o si pada lọ, o si wipe, Kiyesi, i, mo rò ninu mi pe, dajudaju on o jade tọ̀ mi wá, yio si duro, yio si kepè orukọ Oluwa Ọlọrun rẹ̀, yio si fi ọwọ rẹ̀ pa ibẹ̀ na, yio si ṣe awòtan ẹ̀tẹ na.

12 Abana ati Farpari, awọn odò Damasku kò ha dara jù gbogbo awọn omi Israeli lọ? emi kì iwẹ̀ ninu wọn ki emi si mọ́? Bẹ̃li o yipada, o si jade lọ ni irúnu.

13 Awọn iranṣẹ rẹ̀ si sunmọ ọ, nwọn si ba a sọ̀rọ, nwọn si wipe, Baba mi, woli iba wi fun ọ pe, ki o ṣe ohun nla kan, iwọ kì ba ti ṣe e bi? melomelo, nigbati o wi fun ọ pe, Wẹ̀, ki o si mọ́?

14 Nigbana ni o sọ̀kalẹ, o si tẹ̀ ara rẹ̀ bọ inu Jordani nigba meje, gẹgẹ bi ọ̀rọ enia Ọlọrun: ẹran-ara rẹ̀ si tún pada bọ̀ gẹgẹ bi ẹran-ara ọmọ kekere, on si mọ́.

15 O si pada tọ̀ enia Ọlọrun na lọ, on, ati gbogbo ẹgbẹ́ rẹ̀, nwọn si wá, nwọn duro niwaju rẹ̀: on si wipe, wõ, nisisiyi ni mo to mọ̀ pe, Kò si Ọlọrun ni gbogbo aiye, bikòṣe ni Israeli: njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, gbà ẹbun lọwọ iranṣẹ rẹ.

16 Ṣugbọn on wipe, Bi Oluwa ti mbẹ, niwaju ẹniti emi duro, emi kì yio gbà nkan. O si rọ̀ ọ ki o gbà, ṣugbọn on kọ̀.

17 Naamani si wipe, Njẹ, emi bẹ̀ ọ, a kì yio ha fi erupẹ ẹrù ibàka meji fun iranṣẹ rẹ? nitori lati oni lọ iranṣẹ rẹ kì yio rubọ sisun, bẹ̃ni kì yio rubọ si awọn ọlọrun miran, bikòṣe si Oluwa.