2. A. Ọba 5:14-20 YCE

14 Nigbana ni o sọ̀kalẹ, o si tẹ̀ ara rẹ̀ bọ inu Jordani nigba meje, gẹgẹ bi ọ̀rọ enia Ọlọrun: ẹran-ara rẹ̀ si tún pada bọ̀ gẹgẹ bi ẹran-ara ọmọ kekere, on si mọ́.

15 O si pada tọ̀ enia Ọlọrun na lọ, on, ati gbogbo ẹgbẹ́ rẹ̀, nwọn si wá, nwọn duro niwaju rẹ̀: on si wipe, wõ, nisisiyi ni mo to mọ̀ pe, Kò si Ọlọrun ni gbogbo aiye, bikòṣe ni Israeli: njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, gbà ẹbun lọwọ iranṣẹ rẹ.

16 Ṣugbọn on wipe, Bi Oluwa ti mbẹ, niwaju ẹniti emi duro, emi kì yio gbà nkan. O si rọ̀ ọ ki o gbà, ṣugbọn on kọ̀.

17 Naamani si wipe, Njẹ, emi bẹ̀ ọ, a kì yio ha fi erupẹ ẹrù ibàka meji fun iranṣẹ rẹ? nitori lati oni lọ iranṣẹ rẹ kì yio rubọ sisun, bẹ̃ni kì yio rubọ si awọn ọlọrun miran, bikòṣe si Oluwa.

18 Ninu nkan yi ni ki Oluwa ki o darijì iranṣẹ rẹ, nigbati oluwa mi ba lọ si ile Rimmoni lati foribalẹ nibẹ, ti on ba si fi ara tì ọwọ mi, ti emi tẹ̀ ara mi ba ni ile Rimmoni: nigbati mo ba tẹ̀ ara mi ba ni ile Rimmoni, ki Oluwa ki o darijì iranṣẹ rẹ ninu nkan yi.

19 On si wi fun u pe, Mã lọ ni alãfia. Bẹ̃ni o si jade lọ jinà diẹ kuro lọdọ rẹ̀.

20 Ṣugbọn Gehasi, iranṣẹ Eliṣa enia Ọlọrun na wipe, Kiyesi i, oluwa mi ti dá Naamani ara Siria yi si, niti kò gbà nkan ti o mu wá lọwọ rẹ̀: ṣugbọn, bi Oluwa ti mbẹ, emi o sare bá a, emi o si gbà nkan lọwọ rẹ̀.