Neh 10:28-34 YCE

28 Ati awọn enia iyokù, awọn alufa, awọn ọmọ Lefi, awọn adèna, awọn akọrin, awọn Netinimu, ati gbogbo awọn ti o ya ara wọn kuro lọdọ awọn enia ilẹ na si ofin Ọlọrun, aya wọn, awọn ọmọ wọn ọkunrin, ati awọn ọmọ wọn obinrin, gbogbo ẹniti o ni ìmọ ati oye;

29 Nwọn faramọ awọn arakunrin wọn, awọn ijoye wọn, nwọn si wọ inu èpe ati ibura, lati ma rìn ninu ofin Ọlọrun, ti a fi lelẹ nipa ọwọ Mose iranṣẹ Ọlọrun, lati kiyesi, ati lati ṣe gbogbo aṣẹ Jehofah, Oluwa wa, ati idajọ rẹ̀, ati ilana rẹ̀;

30 Ati pe awa kì yio fi awọn ọmọbinrin wa fun awọn enia ilẹ na, bẹ̃li awa kì yio fẹ ọmọbinrin wọn fun awọn ọmọ wa.

31 Bi awọn enia ilẹ na ba mu ọjà tabi ohun jijẹ wa li ọjọ isimi lati tà, awa kì yio rà a li ọwọ wọn li ọjọ isimi, tabi li ọjọ mimọ́: awa o si fi ọdun keje silẹ, ati ifi-agbara-gba gbèse.

32 Awa si ṣe ilàna fun ara wa pe, ki olukuluku ma san idamẹta ṣekeli li ọdọdun fun iṣẹ ile Ọlọrun wa.

33 Nitori àkara ifihàn, ati nitori ẹbọ ohun jijẹ igbagbogbo, ati nitori ẹbọ sisun igbagbogbo, ti ọjọ isimi, ti oṣù titun, ti àse ti a yàn, ati nitori ohun mimọ́, ati nitori ẹbọ ẹ̀ṣẹ lati ṣe ètutu fun Israeli, ati fun gbogbo iṣẹ ile Ọlọrun wa.

34 Awa si dìbo larin awọn alufa awọn ọmọ Lefi, ati awọn enia, fun ọrẹ igi, lati mu u wá si ile Ọlọrun wa, gẹgẹ bi idile awọn baba wa li akoko ti a yàn li ọdọdun, lati fi daná li ori pẹpẹ Oluwa Ọlọrun wa, gẹgẹ bi a ti kọ ọ ninu ofin.