Neh 10:31-37 YCE

31 Bi awọn enia ilẹ na ba mu ọjà tabi ohun jijẹ wa li ọjọ isimi lati tà, awa kì yio rà a li ọwọ wọn li ọjọ isimi, tabi li ọjọ mimọ́: awa o si fi ọdun keje silẹ, ati ifi-agbara-gba gbèse.

32 Awa si ṣe ilàna fun ara wa pe, ki olukuluku ma san idamẹta ṣekeli li ọdọdun fun iṣẹ ile Ọlọrun wa.

33 Nitori àkara ifihàn, ati nitori ẹbọ ohun jijẹ igbagbogbo, ati nitori ẹbọ sisun igbagbogbo, ti ọjọ isimi, ti oṣù titun, ti àse ti a yàn, ati nitori ohun mimọ́, ati nitori ẹbọ ẹ̀ṣẹ lati ṣe ètutu fun Israeli, ati fun gbogbo iṣẹ ile Ọlọrun wa.

34 Awa si dìbo larin awọn alufa awọn ọmọ Lefi, ati awọn enia, fun ọrẹ igi, lati mu u wá si ile Ọlọrun wa, gẹgẹ bi idile awọn baba wa li akoko ti a yàn li ọdọdun, lati fi daná li ori pẹpẹ Oluwa Ọlọrun wa, gẹgẹ bi a ti kọ ọ ninu ofin.

35 Ati lati mu akọso ilẹ wa wá, ati gbogbo akọso eso igi gbogbo, li ọdọdun si ile Oluwa wa:

36 Pẹlu akọbi awọn ọmọ wa ọkunrin, ati ti ohun ọ̀sin wa, gẹgẹ bi ati kọ ninu ofin, akọbi awọn ẹran-nla wa, ati ti agutan wa, lati mu wọn wá si ile Ọlọrun wa, fun awọn alufa ti nṣiṣẹ ni ile Ọlọrun wa.

37 Ki awa si mu akọso iyẹfun pipò wa wá, ati ọrẹ wa, ati eso oniruru igi wa, ti ọti-waini ati ti ororo fun awọn alufa, si iyẹwu ile Ọlọrun wa, ati idamẹwa ilẹ wa fun awọn ọmọ Lefi, ki awọn ọmọ Lefi ki o le ni idamẹwa ninu gbogbo ilu arọko wa.