4 Nigbana ni ọba wi fun mi pe, ẹ̀bẹ kini iwọ fẹ bẹ̀? Bẹ̃ni mo gbadura si Ọlọrun ọrun.
5 Mo si wi fun ọba pe, Bi o ba wù ọba, ati bi iranṣẹ rẹ ba ri ojurere lọdọ rẹ, ki iwọ le rán mi lọ si Juda, si ilu iboji awọn baba mi, ki emi ki o ba le kọ́ ọ.
6 Ọba si wi fun mi pe, (ayaba si joko tì i) ajo rẹ yio ti pẹ to? nigbawo ni iwọ o si pada? Bẹli o wù ọba lati rán mi; mo si dá àkoko kan fun u.
7 Pẹlupẹlu mo wi fun ọba pe, bi o ba wù ọba, ki o fun mi ni iwe si awọn bãlẹ li oke odò, ki nwọn le mu mi kọja titi emi o fi de Juda;
8 Ati iwe kan fun Asafu, oluṣọ igbo ọba, ki o le fun mi ni igi fun atẹrigba ẹnu-ọ̀na odi lẹba ile Ọlọrun ati fun odi ilu, ati fun ile ti emi o wọ̀. Ọba si fun mi gẹgẹ bi ọwọ rere Ọlọrun mi lara mi.
9 Nigbana ni mo de ọdọ awọn bãlẹ li oke odo mo si fi iwe ọba fun wọn: Ọba si ti rán awọn olori-ogun ati ẹlẹṣin pẹlu mi.
10 Nigbati Sanballati ara Horoni ati Tobiah iranṣẹ ara Ammoni gbọ́, o bi wọn ni inu gidigidi pe, enia kan wá lati wá ire awọn ọmọ Israeli.