13 Mo si gbọ̀n apo aṣọ mi, mo si wipe, Bayi ni ki Ọlọrun ki o gbọ̀n olukuluku enia kuro ni ile rẹ̀, ati kuro ninu iṣẹ rẹ̀, ti kò mu ileri yi ṣẹ, ani bayi ni ki a gbọ̀n ọ kuro, ki o si di ofo. Gbogbo ijọ si wipe, Amin! nwọn si fi iyìn fun Oluwa. Awọn enia na si ṣe gẹgẹ bi ileri yi.
14 Pẹlupẹlu lati akoko ti a ti yàn mi lati jẹ bãlẹ wọn ni ilẹ Juda, lati ogún ọdun titi de ọdun kejilelọgbọn Artasasta ọba, eyinì ni, ọdun mejila, emi ati awọn arakunrin mi kò jẹ onjẹ bãlẹ.
15 Ṣugbọn awọn bãlẹ iṣaju, ti o ti wà, ṣaju mi, di ẹrù wiwo le lori awọn enia, nwọn si ti gbà akara ati ọti-waini, laika ogoji ṣekeli fadaka; pẹlupẹlu awọn ọmọkunrin wọn tilẹ lo agbara lori enia na: ṣugbọn emi kò ṣe bẹ̃ nitori ibẹ̀ru Ọlọrun.
16 Mo si mba iṣẹ odi yi lọ pẹlu, awa kò si rà oko kan: gbogbo awọn ọmọkunrin mi li o si gbajọ sibẹ si iṣẹ na.
17 Pẹlupẹlu awọn ti o joko ni tabili mi jẹ ãdọjọ enia ninu awọn ara Juda ati ninu awọn ijoye, laika awọn ti o wá sọdọ wa lati ãrin awọn keferi ti o wà yi wa ka.
18 Njẹ ẹran ti a pese fun mi jẹ malũ kan ati ãyo agutan mẹfa; fun ijọ kan ni a pese adiẹ fun mi pẹlu, ati lẹ̃kan ni ijọ mẹwa onirũru ọti-waini: ṣugbọn fun gbogbo eyi emi kò bere onjẹ bãlẹ, nitori iṣẹ na wiwo lori awọn enia yi.
19 Ranti mi, Ọlọrun mi, fun rere, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti mo ti ṣe fun enia yi.