62 Awọn ọmọ Delaiah, awọn ọmọ Tobiah, awọn ọmọ Nekoda, ojilelẹgbẹta ole meji.
63 Ati ninu awọn alufa: awọn ọmọ Habaiah, awọn ọmọ Kosi, awọn ọmọ Barsillai, ti o ni ọkan ninu awọn ọmọbinrin Barsillai, ara Gileadi, li aya, a si npè e nipa orukọ wọn.
64 Awọn wọnyi wá iwe orukọ wọn ninu awọn wọnyi ti a kọ orukọ wọn nipa idile ṣugbọn a kò ri i: nitorina li a ṣe yà wọn kurò ninu oyè alufa.
65 Bãlẹ na si wi fun wọn pe, ki nwọn máṣe jẹ ninu ohun mimọ́ julọ, titi alufa kan yio fi duro pẹlu Urimu, ati Tummimu,
66 Iye gbogbo ijọ jasi ẹgbãmọkanlelogun o le ojidinirinwo.
67 Laikà awọn iranṣẹkunrin wọn ati iranṣẹ-binrin wọn, iye wọn jẹ ẹgbẹtadilẹgbãrin o di ẹtalelọgọta: nwọn si ni ojilugba o le marun akọni ọkunrin ati akọni obinrin.
68 Ẹṣin wọn jẹ ọtadilẹgbẹrin o di mẹrin: ibaka nwọn jẹ ojilugba o le marun: