10 Emi o si tú ẹmi ore-ọfẹ ati ẹbẹ sori ile Dafidi ati sori Jerusalemu: nwọn o si ma wò mi ẹniti nwọn ti gún li ọ̀kọ, nwọn o si ma ṣọ̀fọ rẹ̀, gẹgẹ bi enia ti nṣọ̀fọ fun ọmọ ọkunrin rẹ̀ kanṣoṣo, nwọn o si wà ni ibanujẹ, bi ẹniti mbanujẹ fun akọbi rẹ̀.
11 Li ọjọ na li ọ̀fọ nlanlà yio wà ni Jerusalemu, gẹgẹ bi ọ̀fọ Hadadrimmoni li afonifoji Megiddoni.
12 Ilẹ na yio ṣọ̀fọ, idile idile lọtọ̀tọ; idile Dafidi lọ́tọ̀; ati awọn aya wọn lọ́tọ̀; idile Natani lọ́tọ̀, ati awọn aya wọn lọtọ̀.
13 Idile Lefi lọ́tọ̀, ati awọn aya wọn lọ́tọ̀; idile Ṣimei lọ́tọ̀, ati awọn aya wọn lọ́tọ̀.
14 Gbogbo awọn idile ti o kù, idile idile lọtọ̀tọ, ati awọn aya wọn lọ́tọ̀.