1 Ọ̀RỌ Oluwa awọn ọmọ-ogun si tun tọ̀ mi wá, wipe,
2 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; owu nlanla ni mo jẹ fun Sioni, ikannu nlanla ni mo fi jowu fun u.
3 Bayi li Oluwa wi; Mo ti yipada si Sioni emi o si gbe ãrin Jerusalemu: a o si pè Jerusalemu ni ilu nla otitọ; ati oke nla Oluwa awọn ọmọ-ogun, okenla mimọ́ nì.
4 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, arugbo ọkunrin ati arugbo obinrin, yio sa gbe igboro Jerusalemu, ati olukuluku ti on ti ọ̀pa li ọwọ rẹ̀ fun ogbó.
5 Igboro ilu yio si kún fun ọmọdekunrin, ati ọmọdebinrin, ti nṣire ni ita wọn.