19 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe; Ãwẹ̀ oṣù kẹrin, ati ti oṣù karun, ati ãwẹ̀ oṣù keje, ati ti ẹkẹwa, yio jẹ ayọ̀, ati didùn inu, ati apejọ ariya fun ile Juda; nitorina ẹ fẹ́ otitọ ati alafia.
20 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe; Awọn enia yio sa tún wá, ati ẹniti yio gbe ilu-nla pupọ.
21 Awọn ẹniti ngbe ilu-nla kan yio lọ si omiran, wipe, Ẹ jẹ ki a yára lọ igbadura niwaju Oluwa, ati lati wá Oluwa awọn ọmọ-ogun: emi pẹlu o si lọ.
22 Nitõtọ ọ̀pọlọpọ enia, ati awọn alagbara orilẹ-ède yio wá lati wá Oluwa awọn ọmọ-ogun ni Jerusalemu; ati lati gbadura niwaju Oluwa.
23 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe, li ọjọ wọnni yio ṣẹ, ni ọkunrin mẹwa lati inu gbogbo ède ati orilẹ-ède yio dì i mú, ani yio dì eti aṣọ ẹniti iṣe Ju mu, wipe, A o ba ọ lọ, nitori awa ti gbọ́ pe, Ọlọrun wà pẹlu rẹ.