11 O si ri ọrun ṣí, ohun elo kan si sọkalẹ bi gọgọwú nla, ti a ti igun mẹrẹrin, sọkalẹ si ilẹ.
12 Ninu rẹ̀ li olorijorí ẹranko ẹlẹsẹ mẹrin wà, ati ohun ti nrakò li aiye ati ẹiyẹ oju ọrun.
13 Ohùn kan si fọ̀ si i pe, Dide, Peteru; mã pa ki o si mã jẹ.
14 Ṣugbọn Peteru dahùn pe, Agbẹdọ, Oluwa; nitori emi kò jẹ ohun èwọ ati alaimọ́ kan ri.
15 Ohùn kan si tún fọ̀ si i lẹkeji pe, Ohun ti Ọlọrun ba ti wẹ̀nu, iwọ máṣe pè e li èwọ mọ́.
16 Eyi si ṣe li ẹrinmẹta: lojukanna a si gbé ohun elo na pada lọ soke ọrun.
17 Bi o si ti ngọ́ Peteru ninu ara rẹ̀ bi a ba ti mọ̀ iran ti on ri yi si, si wo o, awọn ọkunrin ti a rán ti ọdọ Korneliu wá de, nwọn mbère ile Simoni, nwọn duro li ẹnu-ọ̀na,