44 Bi Peteru si ti nsọ ọ̀rọ wọnyi li ẹnu, Ẹmí Mimọ́ bà le gbogbo awọn ti o gbọ́ ọ̀rọ na.
45 Ẹnu si yà awọn onigbagbọ ti ìkọlà, iye awọn ti o ba Peteru wá, nitoriti a tu ẹbùn Ẹmi Mimọ́ sori awọn Keferi pẹlu.
46 Nitori nwọn gbọ́, nwọn nfọ onirũru ède, nwọn si nyìn Ọlọrun logo. Nigbana ni Peteru dahùn wipe,
47 Ẹnikẹni ha le ṣòfin omi, ki a má baptisi awọn wọnyi, ti nwọn gbà Ẹmí Mimọ́ bi awa?
48 O si paṣẹ ki a baptisi wọn li orukọ Jesu Kristi. Nigbana ni nwọn bẹ̀ ẹ ki o duro ni ijọ melokan.