5 Si rán enia nisisiyi lọ si Joppa, ki nwọn si pè Simoni wá, ẹniti apele rẹ̀ jẹ Peteru:
6 O wọ̀ si ile ẹnikan Simoni alawọ, ti ile rẹ̀ wà leti okun: on ni yio sọ fun ọ bi iwọ o ti ṣe.
7 Nigbati angẹli na ti o ba Korneliu sọ̀rọ si fi i silẹ lọ, o pè meji ninu awọn iranṣẹ ile rẹ̀, ati ọmọ-ogun olufọkànsin kan, ninu awọn ti ima duro tì i nigbagbogbo;
8 Nigbati o si ti rohin ohun gbogbo fun wọn, o rán wọn lọ si Joppa.
9 Ni ijọ keji bi nwọn ti nlọ li ọ̀na àjo wọn, ti nwọn si sunmọ ilu na, Peteru gùn oke ile lọ igbadura niwọn wakati kẹfa ọjọ:
10 Ebi si pa a gidigidi, on iba si jẹun: ṣugbọn nigbati nwọn npèse, o bọ si ojuran,
11 O si ri ọrun ṣí, ohun elo kan si sọkalẹ bi gọgọwú nla, ti a ti igun mẹrẹrin, sọkalẹ si ilẹ.