17 Ọlọrun awọn enia Israeli yi, yàn awọn baba wa, o si gbé awọn enia na leke, nigbati nwọn ṣe atipo ni ilẹ Egipti, apá giga li o si fi mu wọn jade kuro ninu rẹ̀.
18 Ni ìwọn igba ogoji ọdún li o fi mu sũru fun ìwa wọn ni ijù.
19 Nigbati o si ti run orilẹ-ède meje ni ilẹ Kenaani, o si fi ilẹ wọn fun wọn ni ini fun iwọn ãdọta-le-ni-irinwo ọdun.
20 Ati lẹhin nkan wọnyi o fi onidajọ fun wọn, titi o fi di igba Samueli woli.
21 Ati lẹhinna ni nwọn bère ọba: Ọlọrun si fun wọn ni Saulu ọmọ Kiṣi, ọkunrin kan ninu ẹ̀ya Benjamini, fun ogoji ọdún.
22 Nigbati o si mu u kuro, o gbé Dafidi dide li ọba fun wọn; ẹniti o si jẹri rẹ̀ pe, Mo ri Dafidi ọmọ Jesse ẹni bi ọkàn mi, ti yio ṣe gbogbo ifẹ mi.
23 Lati inu iru-ọmọ ọkunrin yi ni Ọlọrun ti gbe Jesu Olugbala dide fun Israeli gẹgẹ bi ileri,