4 Njẹ bi a ti rán wọn lati ọwọ́ Ẹmí Mimọ́ lọ, nwọn sọkalẹ lọ si Seleukia; lati ibẹ̀ nwọn si wọkọ̀ lọ si Kipru.
5 Nigbati nwọn si wà ni Salami, nwọn nwasu ọ̀rọ Ọlọrun ni sinagogu awọn Ju: nwọn si ni Johanu pẹlu fun iranṣẹ wọn.
6 Nigbati nwọn si là gbogbo erekùṣu já de Pafo, nwọn ri ọkunrin kan, oṣó, woli eke, Ju, orukọ ẹniti ijẹ Barjesu,
7 Ẹniti o wà lọdọ Sergiu Paulu bãlẹ ilu na, amoye enia. On na li o ranṣẹ pè Barnaba on Saulu, o si fẹ gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun.
8 Ṣugbọn Elima oṣó na (nitori bẹ̃ni itumọ̀ orukọ rẹ̀) o takò wọn, o nfẹ pa bãlẹ ni ọkàn da kuro ni igbagbọ́.
9 Ṣugbọn Saulu (ti a si npè ni Paulu), o kún fun Ẹmí Mimọ́, o si tẹjumọ́ ọ, o si wipe,
10 Iwọ ti o kún fun arekereke gbogbo, ati fun iwà-ìka gbogbo, iwọ ọmọ Eṣu, iwọ ọta ododo gbogbo, iwọ kì yio ha dẹkun ati ma yi ọna titọ́ Oluwa po?