1 NIGBATI nwọn si ti kọja Amfipoli ati Apollonia, nwọn wá si Tessalonika, nibiti sinagogu awọn Ju wà:
2 Ati Paulu, gẹgẹbi iṣe rẹ̀, o wọle tọ̀ wọn lọ, li ọjọ isimi mẹta o si mba wọn fi ọ̀rọ we ọ̀rọ ninu iwe-mimọ́,
3 O ntumọ, o si nfihàn pe, Kristi kò le ṣaima jìya, ki o si jinde kuro ninu okú; ati pe, Jesu yi, ẹniti emi nwasu fun nyin, on ni Kristi na.
4 A si yi ninu wọn lọkàn pada, nwọn si darapọ̀ mọ́ Paulu on Sila; ati ninu awọn olufọkansìn Hellene ọ̀pọ pupọ, ati ninu awọn obinrin ọlọlá, kì iṣe diẹ.
5 Ṣugbọn awọn Ju jowu, nwọn si fà awọn jagidijagan ninu awọn ijajẹ enia mọra, nwọn gbá ẹgbẹ jọ, nwọn si nrú ilu; nwọn si kọlù ile Jasoni, nwọn nfẹ mu wọn jade tọ̀ awọn enia wá.
6 Nigbati nwọn kò si ri wọn, nwọn wọ́ Jasoni, ati awọn arakunrin kan tọ̀ awọn olori ilu lọ, nwọn nkigbe pe, Awọn wọnyi ti o ti yi aiye po wá si ihinyi pẹlu;