30 Pẹlupẹlu igba aimọ̀ yi li Ọlọrun ti foju fò da; ṣugbọn nisisiyi o paṣẹ fun gbogbo enia nibi gbogbo lati ronupiwada:
31 Niwọnbi o ti da ọjọ kan, ninu eyi ti yio ṣe idajọ aiye li ododo, nipasẹ ọkunrin na ti o ti yàn, nigbati o ti fi ohun idaniloju fun gbogbo enia, niti o jí i dide kuro ninu okú.
32 Nigbati nwọn ti gbọ́ ti ajinde okú, awọn miran nṣẹ̀fẹ: ṣugbọn awọn miran wipe, Awa o tún nkan yi gbọ́ li ẹnu rẹ.
33 Bẹ̃ni Paulu si jade kuro larin wọn.
34 Ṣugbọn awọn ọkunrin kan fi ara mọ́ ọ, nwọn si gbagbọ́: ninu awọn ẹniti Dionisiu ara Areopagu wà, ati obinrin kan ti a npè ni Damari, ati awọn miran pẹlu wọn.