4 A si yi ninu wọn lọkàn pada, nwọn si darapọ̀ mọ́ Paulu on Sila; ati ninu awọn olufọkansìn Hellene ọ̀pọ pupọ, ati ninu awọn obinrin ọlọlá, kì iṣe diẹ.
5 Ṣugbọn awọn Ju jowu, nwọn si fà awọn jagidijagan ninu awọn ijajẹ enia mọra, nwọn gbá ẹgbẹ jọ, nwọn si nrú ilu; nwọn si kọlù ile Jasoni, nwọn nfẹ mu wọn jade tọ̀ awọn enia wá.
6 Nigbati nwọn kò si ri wọn, nwọn wọ́ Jasoni, ati awọn arakunrin kan tọ̀ awọn olori ilu lọ, nwọn nkigbe pe, Awọn wọnyi ti o ti yi aiye po wá si ihinyi pẹlu;
7 Awọn ẹniti Jasoni gbà si ọdọ: gbogbo awọn wọnyi li o si nhuwa lodi si aṣẹ Kesari, wipe, ọba miran kan wà, Jesu.
8 Awọn enia ati awọn olori ilu kò ni ibalẹ aiya nigbati nwọn gbọ́ nkan wọnyi.
9 Nigbati nwọn si gbà ogò lọwọ Jasoni ati awọn iyokù, nwọn jọwọ lọ.
10 Lọgan awọn arakunrin si rán Paulu on Sila lọ si Berea li oru: nigbati nwọn si de ibẹ̀, nwọn wọ̀ inu sinagogu awọn Ju lọ.