15 Ṣugbọn bi o ba ṣe ọ̀ran nipa ọ̀rọ ati orukọ, ati ti ofin nyin ni, ki ẹnyin ki o bojuto o fun ara nyin, nitoriti emi kò fẹ ṣe onidajọ nkan bawọnni.
16 O si lé wọn kuro ni ibi itẹ idajọ.
17 Gbogbo awọn Hellene si mu Sostene, olori sinagogu, nwọn si lù u niwaju itẹ idajọ. Gallioni kò si ṣú si nkan wọnyi.
18 Paulu si duro si i nibẹ̀ li ọjọ pipọ, nigbati o si dágbere fun awọn arakunrin, o ba ti ọkọ̀ lọ si Siria, ati Priskilla ati Akuila pẹlu rẹ̀; o ti fá ori rẹ̀ ni Kenkrea: nitoriti o ti jẹjẹ.
19 O si sọkalẹ wá si Efesu, o si fi wọn silẹ nibẹ̀: ṣugbọn on tikararẹ̀ wọ̀ inu sinagogu lọ, o si ba awọn Ju fi ọrọ we ọrọ.
20 Nigbati nwọn si bẹ̀ ẹ pe, ki o ba awọn joko diẹ si i, o kọ̀;
21 Ṣugbọn o dágbere fun wọn, o si wipe, Emi kò gbọdọ ṣaima ṣe ajọ ọdún ti mbọ̀ yi ni Jerusalemu bi o ti wù ki o ri: ṣugbọn emi ó tún pada tọ̀ nyin wá, bi Ọlọrun ba fẹ. O si ṣikọ̀ ni Efesu.