17 Ati lati Miletu o ranṣẹ si Efesu, lati pè awọn alàgba ijọ wá sọdọ rẹ̀.
18 Nigbati nwọn si de ọdọ rẹ̀, o wi fun wọn pe, Ẹnyin tikaranyin mọ̀, lati ọjọ ikini ti mo ti de Asia, bi emi ti ba nyin gbé, ni gbogbo akoko na,
19 Bi mo ti nfi ìrẹlẹ ọkàn gbogbo sìn Oluwa, ati omije pipọ, pẹlu idanwò, ti o bá mi, nipa ìdena awọn Ju:
20 Bi emi kò ti fà sẹhin lati sọ ohunkohun ti o ṣ'anfani fun nyin, ati lati mã kọ́ nyin ni gbangba ati lati ile de ile,
21 Ti mo nsọ fun awọn Ju, ati fun awọn Hellene pẹlu, ti ironupiwada sipa Ọlọrun, ati ti igbagbọ́ sipa Jesu Kristi Oluwa wa.
22 Njẹ nisisiyi, wo o, ọkàn mi nfà si ati lọ si Jerusalemu, laimọ̀ ohun ti yio bá mi nibẹ̀:
23 Bikoṣe bi Ẹmí Mimọ́ ti nsọ ni ilu gbogbo pe, ìde on ìya mbẹ fun mi.